Yoruba Songs LyricsPedia: Ultimate List of 200 Yoruba Gospel Songs Lyrics & Videos
One of our new year resolution is to promote heavenly musics, songs and videos the best way we can and to the right audience.
Here is bringing to you the ultimate list of 200 Gospel songs in Yoruba language. Listed with it, is their lyrics in-full, YouTube videos and sharing methods.
This is a huge improvement on our earlier post on Top 15 Yoruba Gospel music Lyrics.
Contents:
The List
Today’s list is separated into four (4) pages for a better navigation. You can use the NEXT and PREVIOUS buttons to browse through the entire contents.
Remember to remind us of any other Yoruba Worship songs we missed out on by using the comment section below.
1. N Ko ni pada, n ko ni pada
The Full Lyrics
Mo ti pinnu lati tele Jesu (3x)
N Ko ni pada, N Ko ni pada.
Mo n w’agbelebu, aye n be lehin (3x)
N Ko ni pada, N Ko ni pada.
Gba gbogo aye, fun mi ni Jesu (3x)
N Ko ni pada, N Ko ni pada.
B’o s’emi nikan, n o sin Jesu (3x)
N Ko ni pada, N Ko ni pada
Olorun n pese ijoba miiran (3x)
N Ko ni pada, N Ko ni pada
The Video
2. Jesu tun n pada bo
The Full Lyrics
Jesu tun n pada bo (2x)
O g’oke lo, O se ‘leri
P’oun yoo tun pada wa
Jesu tun n pada bo (2x)
Ogo, Alleluyah
Jesu tun n pada bo
The Video
3. O seun t’O gba mi la
The Full Lyrics
O seun t’O gba mi la, O suen o (2x)
- O seun t’O wo mi san,
- O suen mo d’atunbi.
- O suen t’O da mi n’de
4. Olorun Suen
The Full Lyrics
- Olorun Suen (3x)
Olorun Suen fun mi
- Mo feran Re (3x)
- Emi yoo yin In (3x)
- Oun yoo pese
5. Ni oruko Jes
The Full Lyrics
Ni oruko Jesu (2x)
Ti’wa ni isegun
Ni oruko Jesu (2x)
satani yoo sa lo.
t’a ba wa ni oruko Jesu
taa l’o le d’oju ija ko wa
ni oruko Jesu Kristi
Ti’wa ni isegun
6. Ma se fo’ya mo
The Full Lyrics
Ma se fo’ya mo, a ti segun
Ma se fo’ya mo, a ti segun
7. Jesu Kristi wa gba ‘joba
The Full Lyrics
Jesu Kristi wa gba ‘joba (2x)
Ki gbogbo aye le di t’Oluwa
Jake-jado l’a o k’okiki Jesu Oba wa
Jesu Kristi wa gba ‘joba.
8. Bibeli mimo t’orun
The Full Lyrics
Bibeli mimo t’orun
Oro Re l’o n gba ni la.
The Video
9. Ko mi b’a ti n gbadura
The Full Lyrics
Ko mi b’a ti n gbadura (3x)
Oluwa, ko mi b’a ti n gbadura
10. A n reti Jesu
The Full Lyrics
A n reti Jesu (3x)
A Ko mo ‘gba t’O le de
O le de ni owuro
O le di ni asale
O le de nigbakugba
A ko mo ‘gba t’O le de
11. A fope, a fiyin fun
The Full Lyrics
A fope, a fiyin fun
Olorun, nitori p’O seun
Nitor’ aanu Re duro laelea.
12. Olorun yanu l’a n sin
The Full Lyrics
Olorun yanu l’a n sin (2x)
L’aye ati l’orun
Ko s’eni bii ti Re
Olorun ‘yanu l’a n sin
13. Jesu, awe de
The Full Lyrics
Jesu, awe de (3x)
Awa de l’oni
14. A ti da mi n’ide
The Full Lyrics
A ti da mi n’ide
Mo bo lowo esu
B’iwo naa ba gba Jesu gbo o
A o da n’ide
A ti da mi n’ide
Mo bo l’owo esu
Lat’igba ti mo ti gba Jesu gbo o
Lati di mi n’ide
15. Oun l’agbara mi
The Full Lyrics
Oun l’agbara mi (2x)
Oruko Jesu l’agbara mi
O ga ju gbogbo oruko aye lo
Oruko Jesu l’agbara mi.
Oun n’isegun mi (2x)
Oun n’idande mi (2x)
16. ‘Gba ti mo ba d’orun
The Full Lyrics
‘Gba ti mo ba d’orun
Mo m’emi ti no ri
N o ri Jesu Olugbala
N o ke Alleluyah, Amin
Ke Alleluyah, ke Alleluyah
ke Alleluyah, Amin
17. Ni’gboose, t’owuro ba de
The Full Lyrics
Ni’gboose, t’owuro ba de, Ta o gba awon mimo s’oke
Awa yoo so itan bi a ti segun
Oye yoo tun ye wa si ni igb00se.
18. N’ile Baba mi, opo ibugbe l’o wa
The Full Lyrics
N’ile Baba mi, opo ibugbe l’o wa
N’ile Baba mi (2x)
N’ile Baba mi, opo ibugbe l’o wa
N’ile Baba mi, l’oke
L’ayo, l’ayo, l’a o wo n’ibe (3x)
N’ile Baba mi l’oke.
19. Mo ti d’asegun ..
The Full Lyrics
Mo ti d’asegun… (2x)
Mo ti d’asegun l’onii …
T’okan]t’okan mi ni mo gbagbo
Mo ti d’aegun l’onii.
The Video
20. Yiye l’Odo-agutan
The Full Lyrics
Yiye l’Odo-agutan (2x)
Yiye l’Odo-agutan ti a pa
ogo, Alleluyah (2x)
ogo, Alleluyah, yin Oluwa.
21. Oruko mi n be
The Full Lyrics
Oruko mi ni be (2x)
Oruko mi n be ni orun
Oruko mi n be ninu iwe iye
Oruko mi n be ni orun
22. Mo m’oruko Re
The Full Lyrics
Mo m’oruko Re (2x)
Iyanu l.oruko Re
mo m’oruko Re.
Olorun Alagbara
Oba awon Oba
23. O ti seun pupo fun mi
The Full Lyrics
O ti seun pupo fun mi
Ti n ko le royin tan (3x)
O ti seun pupo fun mi
Ti n ko le royin tan
O ko gbogbo ese mi lo
24. Mo l’Olorun ti ki i kuna
The Full Lyrics
Mo l’Olorun ti ki kuna
Ti ki i kuna, (2x), titi aye.
25. Apata ayeraye
The Full Lyrics
Apata ayeraye
Je ki n sa di O (2x)
Ninu Re l’agbara wo.
Ninu Re n’igbala wa.
Ninu Re n’ibunku wa.
The Video
26. ‘Gba ti mo ronu oore Jesu
The Full Lyrics
‘gba ti mo ronu oore Jesu
At’ohun to ti se fun mi
Okan mi yoo ko’ rin Alleluya
Yin Oluwa t’o gba mi la
27. Mo ti ri ‘ye ailopin
The Full Lyrics
Mo ti ri ‘ye ailopin
‘Tori mo gba A gbo
Jesu ti da mi n’ide
E yin f’oruko Re.
28. Tete ko wa ijoba Olorun
The Full Lyrics
Tete ko wa ijoba Olorun
At’ododo Re
Gbogb’ohun t’o ku l’a o fi kun un fun yin
Allelu, Alleluyah.
Beere, a o si fi i i fun yin
Wa kiri, e o ri
Kankun, a o si i sile fun yin
Allelu Alleluyah
Eeyan ki yoo wa nip’akara nikan
Sugbon nip’Oro
Ti o ti enu Olorun jade wa
Allelu Alleluyah
29. Emi yoo f’ayo s’ise, ise Oluwa
The Full Lyrics
Emi yoo fayo s’ise, ise Oluwa
‘gba m’ba fayo pari ire-ije mi
ade ologo kan n be t’a o fi de mi l’ori
Il ologo kan n be t’emi o maa gbe.
30. Baba f’agbara Re han
The Full Lyrics
Baba f’agbara Re han (2x)
ki gbogbo araye le mo daju wi pe
Jesu nikan l’oba l’ori aye gbogbo
Baba f’agbara Re han.
31. Sa ti gbagbo
The Full Lyrics
Sa ti gbagbo (2x)
Ohun gbogbo ni sise
sa ti gbagbo
Mo ti gbagbo (2x)
Ohun gbogbo ni sise
Mo ti gbagbo
32. Eyi l’ojo
The Full Lyrics
Eyi l’ojo (2x)
T’Oluwa ti da (2x)
A o maa yo (2x)
Inu wa yoo dun (2x)
Eyi lojo t’Oluwa ti da
A o maa yo, inu wa yoo dun
Eyi lojo (2x)
T’Oluwa ti da.
33. Titi lae . . . Oluwa
The Full Lyrics
Titi lae . . . Oluwa
Oro Re kale ni orun
O kale ni orun
Eyin yoo m’otito
Otito yoo si so yin d’ominira
Olorun f’araye
O f’Omo Re kan soso fun wa
34. Agbara (3x) Pentikost’
The Full Lyrics
Agbara (3x) Pentikost’
Bekan naa ni l’onii
B’o ti wu ki won wi
Agbara (3x) Pentikost’
Bekan naa l’o ri l’onii
35. Mo fe Jesu ti Nasaret’
The Full Lyrics
Mo fe Jesu ti Nasaret’
Nitori pe O seun pupo fun mi
O dari gbogb’ese mi ji mi
O ran Emi Mimo si mi
Mo fe Jesu ti Nasaret
36. Ka jumo gbe po
The Full Lyrics
Ka jumo gbe po
Eyi yoo ti dun to, Titit ayeraye
T’a o maa jumo gbe po
T’emi t’Oluwa
37. Yin Oluwa
The Full Lyrics
Yin Oluwa (3x)
Gbogboo eniyan, Yin Oluwa
The Video
38. O ti to fun mi
The Full Lyrics
O ti to fun mi (2x)
Jesu ti Kalfari
O ti to fun mi
The Video
39. Baba wa
The Full Lyrics
Baba wa
Baba wa ti n b ni orun, Amin, Owo f’Ooke Re.
The Video
40. Baba wa ni orun
The Full Lyrics
Baba wa ni orun
A f ‘iyin f”ooko Re
A si wo le fun O
41. O ha mo pe ‘dapo miiran n be ni orun
The Full Lyrics
O ha mo pe ‘dapo miiran n be ni orun?
Mo mo pe ‘dapo miiran n be ni orun.
42. Je ki iri orun se s’okan mi t’oungbe n gbe
The Full Lyrics
Je ki iri orun se s’okan mi t’oungbe n gbe
Je ki iri orun se le mi
Emi Mimo Olubukun gb’akoso
Je ki iri orun se le mi
43. O dara k’a yin Oluwa
The Full Lyrics
O dara k’a yi Oluwa, Alleluyah (3x)
Yin Oluwa, Alleluyah
Yin Oluwa, Alleluyah
44. O ti seun pupo fun mi
The Full Lyrics
O ti seun pupo fun mi
O ti ko gbogbo ese mi lo
O ogo, Alleluyah
Jesu n bo wa mi mi Re’le
45. Mo n g’oke lo nipa ‘gbagbo
The Full Lyrics
Mo n g’oke lo nipa ‘gbagbo
Mo n g’oke lo ni’jo kan
Mo n g’oke lo nipa ‘gbagbo
Lati maa ba Jesu gbe
N o f’aye osi yii sile
N o bo s’inu ogo nla
T’emi ti Jesu Oluwa
Mo n g’oke lo n’ijo kan
46. La mi l’oju, Oluwa
The Full Lyrics
La mi l’oju, Oluwa (3x)
Mo ti setan lati gboran
47. Jesu Ki i kuna, Jesu ki i kuna
The Full Lyrics
Jesu Ki i kuna, Jesu ki i kuna (2x)
Araye le ja o kule
Sugbon Jesu ki i kuna
Ibatan re le ja o kule
Ore re la ja o kule
Araye le ja o kule
Sugbon Jesu ki i kuna
Owo re le ja o kule
Oko re le ja o kule
Aya re la ja o kule
Sugbon Jesu ki i kuna
Baba re le ja o kule
Iya re la ja o kule
Omo re la ja o kule
Sugbon Jesu ki i kuna
48. F’epo s’atupa mi k’o maa jo lo
The Full Lyrics
F’epo s’atupa mi k’o maa jo lo
F’epo s’atupa mi, Oluwa
F’epo s’atupa mi k’o maa jo lo
K’o maa jo lo t’ile yoo fi mo
F’alafia f’okan mi, mu mi sinmi (abbl)
F’ife Re s’okan mi ki n le sin o (abbl)
F’igbabo s’okan mi, ki n gbadura (abbl)
49. Agbara n be, ninu eje Jesu
The Full Lyrics
Agbara n be, ninu eje Jesu
Agbara n be, ninu eje Re
Agbara n be, ninu eje Jesu
Agbara n be, ninu eje Re
Agbara n be, Agbara n be
Agbara n be ninu eje Jesu.
(b) Ibukun (d) Igbala (e) Idande (e) Iwosan (f) Alaafia (g) Dariji
50. A ba mi l’enu ihinere
The Full Lyrics
A ba mi l’enu ihinere (2x)
Nigba ti Jesu ba de o
A ba mi l’enu ihinere.
b) Ko ma ni ba n’ile alawo
d) n’ile oti
e) ni’ile ijo
51. Mo l’ayo pe mo je ti Jesu
The Full Lyrics
Mo l’ayo pe mo je ti jesu
Pe mo je ti Jesu, Pe mo je t’Oluwa
Mo l’ayo pe mo je ti Jesu
Pe mo je ti Jesu, Pe mo je t’Oluwa
52. Mo k’aye yii sile
The Full Lyrics
Mo k’aye yii sile
Mo n to Jesu Kristi lehin
Ere nla ni yoo je
Bi mo ba le f’ori ti i de opin
53. Lati ‘gba ti mo ti gbagbo
The Full Lyrics
Lati ‘gba ti mo ti gbagbo
Jesu ko ti i ja mi kule ri
Oun ko si ni i ja mi kule lae
54. Iyipada de ‘gba mo d’atunbi
The Full Lyrics
Iyipada de ‘gba mo d’atunbi (3x)
Awon o’un ti mo se ri, N ko se won mo (3x)
Iyipada de ‘gba mo d’atunbi
Awon aso ti mo n wo, N ko wo won mo (3x)
Iyipada de ‘gba mo d’atunbi
Awon oti ti mo n mu, N ko mu won mo (3x)
Iyipada de ‘gba mo d’atunbi
Awon ibi ti mo n lo, N ko Re ‘be mo (3x)
Iyipada de ‘gba mo d’atunbi
55. Mo d’ominira
The Full Lyrics
Mo d’ominira
Ninu Jesu Mo d’ominira
56. Ara e ba mi kalo
The Full Lyrics
Ara e ba mi kalo
mo n lo s’ile Kenaan’
Alabaro kan ko si
Bi ko se Jesu nikan
Mo n lo s’ile Kenaan (2x)
A ti ko oruko mi s’inu iwe iye
Emi ko tun ni pada mo
57. Mo mo p’alagbara ni Jesu mi,
The Full Lyrics
Mo mo p’alagbara ni Jesu mi
Mo mo p’alagbara ni Jesu mi
O l’agbara lati s’eto aye mi
O l’agbara lati s’oro mi d’ayo,
Mo mo p’alagbara ni Jesu mi.
58. Ibi t’O ba lo, Jesu n se Rero
The Full Lyrics
Ibi t’O ba lo, Jesu n se ReRo
Oluwosan nla, O w’adete san
‘Gba t’awon aro si ri I
Won bere si i rin
Ibi t’o ba lo
Jesu mi n se rere
N’ibi mo ba lo; emi n se rere
Jesu ti ko mi
O n gbe ninu mi
‘Gba t’awon eeyan ri mi
won n f’ogo fun Un
Nipa oore-ofe, emi n se rere
59. O ju wura lo, O ju wura lo
The Full Lyrics
O ju ‘wura lo, O ju wura lo
Emi Olorun ninu eniyan
J’o’un to j’u wura lo
60. Maa ba Jesu lo
The Full Lyrics
Maa ba Jesu lo (2x)
Awon t’aye ti b’aye lo
Maa ba Jesu lo
61. E yin Oluwa
The Full Lyrics
E yin Oluwa
lowo eni t’ire n san (3x)
E yin Oluwa
Lowo eni t’ire n san
Yin In tit aye
62. Korin, Amin, Amin
The Full Lyrics
Koorin, Amin, Amin
E yo, Amin, Amin
Ogo f’Olorun, Amin, Amin
63. Emi o yin O, Olorun mim
The Full Lyrics
Emi o yin O, Olorun mi (3x)
Emi o yin O titi aye.
64. Mo l’ayo pe mo n lo s’orun
The Full Lyrics
Mo l’ayo pe mo n lo s’orun
Mo l’ayo pe mo n lo s’orun
Yin Oluwa, t’O ko ese mi lo k’emi le ye
Mo l’ayo pe mo n lo s’orun
65. Emi nikan ko
The Full Lyrics
Emi nikan ko (2x)
L’ona ajo mi, Jesu pelu mi,
Emi nikan ko.
66. ‘Wo o ha setan bi Jesu ba de
The Full Lyrics
‘Wo o ha setan bi Jesu ba de (2x)
Emi yoo setan (3x)
Bi Jesu ba de (2x)
67. Oun l’Oluwa ko yi pada
The Full Lyrics
Oun l’Oluwa ko yi pada
Oun l’Oluwa ko yi pada
68. Mo je alayo p’a ti ko ‘ruko mi
The Full Lyrics
Mo je alayo p’a ti ko ‘ruko mi
Mo je alayo p’a ti ko ‘ruko mi
69. Mo feran Jesu, Jesu feran mi
The Full Lyrics
Mo feran Jesu, Jesu feran mi
Ko s’ayida kan t’o le yi mi pada.
70. Alejo ni mi, L’aye yii, l’aye yii
The Full Lyrics
Alejo ni mi, l’aye yii, l’aye yii
Alejo ni mi, Orun n’ile mi.
71. Jesu segun aye
The Full Lyrics
Jesu segun aye
O fun wa n’isegun
‘Segun, ‘segun, ‘segun
72. A ti ra mi pada, Alleluyah
The Full Lyrics
A ti ra mi pada, Alleluyah
Eyi l’o mu mi yo, Alleluyah
A ti ra mi pada (3x)
Nipa eje Jesu
A ti da mi n’ide
Mo ti d’ominira
A ti segun fun mi
A so mi di mimo
73. Otito ni oro naa
The Full Lyrics
Otito ni oro naa
o si ye fun ‘tewogba
Pe Jesu n gba elese la
Ninu won, emi je ‘kan
74. Ore ti Baba se o, o jo mi l’oju
The Full Lyrics
Ore ti Baba se o, o jo l’oju
Ore ti Baba se o, o ya mi l’enu
Baba Oloore o, ope l’oye O
75. Emi y0o gbe O ga
The Full Lyrics
Emi yoo gbe O ga
Olorun Alagbara
Laarin opo eniyan
Emi yoo gbe O ga
76. Mo f’aye mi fun Jesu
The Full Lyrics
Mo f’aye mi fun Jesu (3x)
K’aye mi ba le dara
b) Mo f’ise mi fun Jesu
d) Mo f’ile mi fun Jesu
e) Mo f’ebi mi fun Jesu
77. Ohunkohun ti o de mi l’ona iye
The Full Lyrics
Ohunkohun ti o de mi l’ona iye
Metalokan ba mi mu u kuro
78. N’ibikibi t’o ba lo, Yin Oluwa
The Full Lyrics
N’ibikibi t’o ba lo, Yin Oluwa
Gbe Jesu Kristi ga
si d’oju ti Esu, Alleluyah
79. Emi o yin Oluwa ninu okan mi nigba gbogbo
The Full Lyrics
Emi o yin Oluwa ninu okan mi nigba gbogbo
Emi o yin Oluwa ninu okan mi titi aye
80. ‘Gba t’aeon (‘gba t’awon), Mimo wo’le (mimo wo’le)
The Full Lyrics
‘Gba t’awon (‘gba t’awon), Mimo wo’le (mimo wo’le)
“gba t’awon mimo wo’le
Oluwa jowo ka mi mo won
”Gba t’awon mimo wo’le
81. Mo ti ri, ri isubi satani
The Full Lyrics
Mo ti ti, ri isubu satani,
ogo f’Olorun, Ogo ni fun Jesu,
Mo ti ti, ri isubu satani,
ogo f’Olorun, Amin.
‘Gba ti mo wo otun, mo ri
satani ni’le,
‘Gba ti mo wo otun, mo ri
satani ni’le,
‘Gba ti mo wo otun, mo ri
satani ni’le,
‘Gba ti mo wo otun, mo ri
satani ni’le,
Mo ti ri, ri isunbu Satani
Ogo f’Olorun, Ogo ni fun Jesu
Mo ti ri, ri isubu satani
Ogo f’Olorun, Amin.
82. Oruko Jesu l’agbara
The Full Lyrics
Oruko Jesu l’agbara (2x)
Iku gbo, o sa o,
Arun gbo, o wo le
Oruko Jesu ‘agbara.
83. Oun l’Oba awon oba
The Full Lyrics
Oun l’Oba awon oba
Oun l’Oba
b) E se E l’Oba
d) Ni gbogbo agbaye
e) E se Jesu l’Oba
e) Alagbara giga
84. Jesu fere de — Jesu fere de
The Full Lyrics
Jesu fere de — Jesu fere de
O fere de — Jesu fere de
B’araye ko bi ko gbo, (Jesu…)
B’araye ko bi ko gba, (Jesu…) B’o ti ri l’aye Noa, (Jesu)
Ti won n mu ‘mukumu, (egbe)
Ti ikun – omi de, (Jesu…)
T’o gba gbogbo won lo, (egbe)
ojo-ojo kan n bo wa j’oka
Jesu n bo wa, (Jesu fere de)
O fere de o (Jesu fere de)
Ohun t’o wo n’ikoko (Jesu…)
Yoo farahan kedere, (Jesu…)
Ojo-ojo kan n bo wa j’okan o
O fere de (Jesu fere de)
85. Jerusalemu t’orun
The Full Lyrics
Jerusalemu t’orun
N’ibi t’awon mimo wa
Ibe l’okan mi fe lo
Jesu yoo mu mi de be o
86. Esu gbe o, Jesu ti joba
The Full Lyrics
Esu gbe o, Jesu ti joba (2x)
Gbogbo agbara je ti Jesu t’O jinde
Esu gbe o, Jesu ti joba
b) Esu gbe, Esu gbe o
Abuku kan satani
Esu gbe o
87. Eni ba m’oore Jesu k’o ba mi gbe E ga
The Full Lyrics
Eni ba m’oore Jesu k’o ba mi gbe E ga (2x)
Ogbigba ti n gb’elese, mo juba Re
Titi aye l’emi o maa wo’le fun O
Oba ti ko je k’iji aye mi lo.
88. Maa ba A lo o, ile ologo
The Full Lyrics
Maa ba A lo o, ile ologo
Maa ba A lo o, ile ologo
B’araye ko mi maa ba Jesu lo
B’araye ko mi maa ba Jesu re le ogo
89. Agbara, Agbara
The Full Lyrics
Agbara, Agbara
Olorun mi ko le dibaje laelae
90. Igbala ofe l’a mu wa
The Full Lyrics
Igbala ofe l’a mu wa
Ti Jesu f’eje Re se
Igbala ofe l’a mu wa o
E wa gba igbala ofe o
b) Iwosan
91. Jesu ni Ona, Otito ati Iye
The Full Lyrics
Jesu ni Ona, Otito ati Iye
Enikeni t’o ba gba A gbo
Ko ni i segbe
92. Wo O, wo O ki o ri ‘ye
The Full Lyrics
Wo O, wo O ki o ri ‘ye
Wo O, wo O ki o ri ‘ye
93. N o f’ori ti i, Jesu, n o farada a
The Full Lyrics
N o f’ori ti i, Jesu, n o farada a
N o f’ori ti i, laiwo enikeni
N o maa b’awon die t’aye n kegan rin
N o f’ori ti i,, Jesu, n o farada a.
94. Oluwa O se e, Jesu O seun
The Full Lyrics
Oluwa o se e, Jesu O seun
Oluwa o se e, Baba mo dupe.
a) Nigba kan ri, mo j’elese
Sugbon l’onii, a ti tun mi bi
b) Nigba kan ri, mo j’asako
sugbon l’onii, a ti wa mi ri
c) Nigba kan ri, mo je ole
Sugbon l’onii, Jesu ti gba mi
95. E ba mi gbe Jesu yii ga
The Full Lyrics
E ba mi gbe Jesu yii ga (2x)
Alagbara t’oru ‘banju mi lo
b) E ba mi gbe Jesu ga
Oba nla, Oba to j’oba lo
E gbe Jesu ga
Oba nla, Oba to j’oba lo.
96. Mo l’ore kan ti ki i dojuti-ni
The Full Lyrics
Mo l’ore kan ti ki i dojuti-ni
Mo l’ore kan ti ki i tan ni je
Agbara Re l’o n pin okun niya
Oruko Re l’o n gbani la.
97. Mo je ti Jesu, tu Jesu nikan
The Full Lyrics
Mo je ti Jesu, tu Jesu nikan
Mo je ti Jesu, Olugbala
Mo je ti Jesu, ti Jesu nikan
Emi ki i se ti satani mo.
98. Awa de, Oluwa
The Full Lyrics
Awa de, Oluwa (2x)
Awa de, Olorun wa
Awa de, t’agbara wa se
99. Jesu Oluwa o ma se o
The Full Lyrics
Jesu Oluwa o ma se o
‘Tori mi lo se jiya (2x)
Iku Oro ti n ba ku
Iya ese ti n ba je
Gbogbo Re l’O ti ko lo
Jesu Oluwa O ma se o
‘Tori mi l’O se jiya
100. Ogo ni f’Oluwa
The Full Lyrics
Ogo ni f’Oluwa (3x)
Alleluyah
101. A o pade l’ese Jesu
The Full Lyrics
A o pad l’ese Jesu
N’ibi ti a ko ni ya ‘ra wa
A o ri’ra wa, a o yo mo ‘ra wa
Jesu ni yoo je alaga wa
102. Awa ko’ra jo po si odo
The Full Lyrics
Awa ko’ra jo po si odo (2x)
L’odo Oluwa l’awon eeyan Re o pejopo si
Awa ko’ra jo po odo Jesu
103. Maa reti ‘se-yanu l’ojoojumo
The Full Lyrics
Maa reti ‘se-yanu l’ojoojumo
Maa reti ‘se-yanu l’ojoojumo
t’o ba n reti Olorun yoo w’ona
Lati se ‘yanu fun o l’ojoojumo
104. Ebun t’a fi fun mi, ebun ‘yebiye
The Full Lyrics
Ebun t’a fi fun mi, ebun ‘yebiye
Emi o lo o fun Jesu, Olurapada
‘Gba ti m’ ba si pari ire-ije mi
N o gb’ade ogo ni paradise.
105. L’ojo ‘kehin, l’ojo ‘kehin
The Full Lyrics
l’ojo ‘kehin, l’ojo ‘kehin
Onigbagboo tooto l’a o gba soke
106. oro Re l’o n gba ni la
The Full Lyrics
Oro Re l’o n gba ni la (2x)
Oro Re, oro Re
Oro Re l’o n gba ni la
b) eje Re l’o n wo ni san (2x)
eje Re, eje Re
Eje Re l’o n wo ni san
107. Ayo mi kun
The Full Lyrics
Ayo mi kun (3x)
Nigba ti mo gb’oro Re
B) ide mi ja
D) Inu mi dun
108. Funrugbin igbagbo
The Full Lyrics
Funrugbin igbagbo
Je ki o tan kale (2x)
a) E jadelo s’ibi gbogbo
Ki e lo waasu Oro naa.
b) O to fun o, tabi o po ju
Lati j’ise Eleda Re?
109. Oun yoo se e l’onii, ise-‘yanu nla
The Full Lyrics
Oun yoo se e l’onii, ise-‘yanu nla
Ti eda ko le royin
oun yoo se e l’onii, ise-‘yanu nla
ti eda ko le royin Re tan.
110. Mo ti mo’na iye yii na
The Full Lyrics
Mo ti mo’na iye yii na
Rara, ko yi pada
Jesu l’ona iye naa
T’o lo s’ile ogo
111. Agbara esu da
The Full Lyrics
Agbara esu da
N’ibi ti Jesu n joba
Agbara esu da?
Ko si o, o ti wo
112. Alaafia ni mo wa
The Full Lyrics
Alaafia ni mo wa
Alaafia l’a ri’ra
Ogo ni fun Jehofa
Olorun alaafia
113. Sora, maa gbadura
The Full Lyrics
Sora, maa gbadura (3x)
Adura l’o le segun
114. Mo l’ayo, Pe mo je ti Jesu
The Full Lyrics
Mo l’ayo, Pe mo je ti Jesu
Pe mo je ti Jesu, Pe mo je t’Oluwa
Mo l’ayo, Pe mo je ti Jesu
Pe mo je ti Jesu
Pe mo je t’Oluwa
b) Mo l’ayo pe Jesu l’Ore mi
Jesu l”Ore mi (2x)
Mo l’ayo, pe Jesu l’Ore mi
Jesu l’Ore mi (2x)
115. Jesu fe mi, O ku fun mi
The Full Lyrics
Jesu fe mi, O ku fun mi
Ko s’eni fe mi bii Jesu
116. Oba angeli ati eniyan ku ise
The Full Lyrics
Oba angeli ati eniyan ku ise
Oba angeli ati eniyan ku ise Re o, Baba
117. Ilu mi ni Jerusalem’
The Full Lyrics
Ilu mi i Jerusalem’ (3x)
Yoo ti dun to lati de’be
118. Gbe E ga, gbe E ga o
The Full Lyrics
Gbe E ga, gbe E ga o
Ba mi gb’Oluwa ga (2x)
Oba t’O mu ‘gbala w’aye se
Jesu l’Oba
Ise owo Re o l’onka, iyebiye ni
119. Tete gba Jesu gbo
The Full Lyrics
Tete gba Jesu gbo
K’akoko to koja
‘Gba t’ipe ba dun o,
Atunse ko si mo.
120. Isaiah gbo ohun Oluwa
The Full Lyrics
Isaiah gbo ohun Oluwa
O wi p’emi niyi, Ran mi
Emi ni’i, Ran mi
N’bikibi, n o lo
‘Gba ti m’ ba gbo ohun Oluwa
N o wi p’emi niyi, Ran mi
121. O feran mi l’opolopo
The Full Lyrics
O feran mi l’opolopo (2x)
O ku l’ori gi, lati gba mi la
O feran mi l’opolopo
122. Gbogbo eniyan e yo
The Full Lyrics
Gbogbo eniyan e yo
E yin Oluwa
gbogbo eniyan e yo
E yin Oluwa
123. E yo, e yo
The Full Lyrics
E yo, e yo,
E yo n’nu Oluwa, e yo
Arakunrin — E yo,
Arabinrin — E yo,
Gbogbo ijo — E yo n’nu
Oluwa, e yo
124. Ma je ki satani so o d’omo re
The Full Lyrics
Ma je ki satani so o d’omo re (2x)
sare wa o, sare wa o
wa s’odo Jesu o
Ma je ki satani so o d’omo re
125. Olorun ife, awa yin O o
The Full Lyrics
Olorun ife, awa yin O o
Olorun ife o, awa juba Re
126. Mo ni Baba kan
The Full Lyrics
Mo ni Baba kan
Olodumare, Oba awon oba
Mo ni Baba kan
127. Gba gbogbo ogo, ogo
The Full Lyrics
Gba gbogbo ogo, ogo (2x)
Gba gbogbo ogo o
Olorun mi ti mo gb’oju le
B) Ti re ni ogo, ogo (2x)
128. Jesu dara pupo
The Full Lyrics
Jesu dara pupo,
Jesu wu mi yeye,
Jesu dara pupo,
Oro Re n tu mi l’ara
129. Alleluyah, Jesu joba
The Full Lyrics
Alleluyah, Jesu joba (2x)
satani ko r’owo mi gba mo
Alleluyah, Jesu joba
130. Emi ko ni je k’esu bori ogun naa
The Full Lyrics
Emi ko ni je k’esu bori ogun naa
Emi ko ni bojege pelu re
O le dan mi wo n’inu
O si le dan mi wo l’ode
Emi ko ni je k’esu bori.
131. Oro Olorun ye
The Full Lyrics
Oro Olorun ye
Oro Olorun l’agbara
Oro Olorun ye, Aiku ni titi aye.
132. O je, o je, o je alaini
The Full Lyrics
O je, o je, o je alaini (3x)
Eni ti ko ni Jesu, o je alaini
133. Mo j’okan l’ara won
The Full Lyrics
Mo j’okan l’ara won (3x)
T’a foor’-ofe gba la (2x)
134. O duro ti mi
The Full Lyrics
O duro ti mi
O n be l’ehin mi (2x)
Ajinde at’iye
O n be l’ehin mi.
135. Arakunrin, arabinrin
The Full Lyrics
Arakunrin, arabinrin
T’ewe t’agba, gb’Oluwa ga
Elese t’a dariji, yin Oluwa
136. Alayo ni mi, emi o maa yo
The Full Lyrics
Alayo ni mi, emi o maa yo
Jesu l’ayo mi, e wa ba mi yo.
137. O se, O se o
The Full Lyrics
O se, O se o
O se o, O se Baba
138. Awa n yin, O, Olorun wa
The Full Lyrics
Awa n yin, O, Olorun wa
Awa n jewo Re pe, Iwo l’Oluwa
139. Oluwa, Iwo ni o ye
The Full Lyrics
Oluwa. Iwo ni o ye
Lati gba gbogbo ogo
Nitori Iwo ni O da ohun gbogbo
Oluwa, Iwo ni o ye
140. Taa l’o da bii Re, Oluwa
The Full Lyrics
Taa l’o da bii Re, Oluwa (2x)
Ninu awon alagbara
Taa l’o da bii Re, Ologo ni mimo
Eleru n’iyin ti n s’ohun ‘yanu
ii) Taa l’o da bii (2x)
Olorun mi (2x)
Taa l’o da bii Olorun mi
T’O se ‘leri t’O mu ‘leri se.
141. L’okan mi, l’okan mi
The Full Lyrics
l’okan mi, l’okan mi
Mo fe ri Jesu l’okan mi
ii) l’okan mi, l’okan mi
Mo ti ri Jesu l’okan mi.
b) L’aye mi d) N’ile mi
e) L’ona mi e) L’ebi mi
142. Ogo, ogo, ogo
The Full Lyrics
Ogo, ogo, ogo (3x)
F’Olorun ti n s’ohun nla.
143. Ihinrere Jesu l’o mu aye mi dun
The Full Lyrics
Ihinrere Jesu l’o mu aye mi dun
Ihinrere Jesu l’o mu aye mi dara.
B) Awon okunrin n dupe l’owo Re
N’tori ore t’Ose fun won
‘Gba t’ihinrere ti bere
L’O fun won ni aya rere.
D) Awon obinrin n due l’owo Re
N’tori ore t’O se fun won
‘Gba t’ihinrere ti bere
L’O fun won ni aya rere.
E) Awon obinrin n due l’owo Re
N’tori ore t’O se fun won
‘Gba t’ihinrere ti bere
L’O fun won ni aya rere.
144. Ope l’oye O, Baba Oloore
The Full Lyrics
Ope l’oye O, Baba Oloore
Iyin l’oye O, Olorun wa
Hosana ye o, O se o, Baba
145. O’un t’o ba gbin, iwo yoo ka a
The Full Lyrics
O’un t’o ba gbin, iwo yoo ka a
L’ori oke ni, tabi petele
O’un t’oba gbin, iwo yoo ka a.
146. A yin O, Oba mimo
The Full Lyrics
A yin O, Oba mimo
A yin O, Oloore
A yin O, Olugbala
Oba t’O n s’akooso wa.
147. Ologun l’Oluwa
The Full Lyrics
Ologun l’Oluwa (2x)
Oluwa ni oruko Re
Ologun l’Oluwa
148. Jesu sa je ‘yanu ni gbogbo ona
The Full Lyrics
Jesu sa je ‘yanu ni gbogbo ona
A pe Jesu l’Oba, a pe E l’Oluwa
Awa ko tile m’Oruko t’awa iba pe Jesu
Sugbon Jesu sa je iyanu
149. Ko s’eni mo bi Oluwa
The Full Lyrics
Ko s’eni mo bi Oluwa
Ko s’enin mo bii Re
Ko s’apata miiran bi Olorun
Ko s’eni mo bi Oluwa
150. Ebi ti Jesu ba n gbe
The Full Lyrics
Ebi ti Jesu ba n gbe
Ebi ayo mi (3x)
Ebi ti Jesu ba n gbe
Ebi ayo ni, ebi alayo.
151. Ko soro f’Olugbala
The Full Lyrics
Ko soro f’Olugbala
Ko soro f’Oluwa
Lati s’ekun d’ayo
Ko soro f’Oluwa
152. Mo m’Eni ti mo gbagbo
The Full Lyrics
Mo m’Eni ti mo gbagbo (2x)
ko je fi mi sile
Yoo dide iranlowo
153. A la’mi okun ja, nipa Oro Re
The Full Lyrics
A la’mo okun ja, nipa Oro Re (2x)
Awa omo Jesu, a la mi okun ja
Awon omo esu l’agbami okun gbe lo
154. Olorun t’O n fina dahun
The Full Lyrics
Olorun t’O n fina dahun
Ni Olorun mi
Olorun t’O n fina dahun
Ni Olorun mi.
b) Olorun t’O gbo t’Elijah.
d) Olorun t’O gbo t’Elisa
e) Olorun t’O gbo ti Mose
e) Olorun t’O ti Kristi.
155. Ayanfe duro, ma se rewesi
The Full Lyrics
Ayanfe duro, ma se rewesi
Ayanfe duro, ma se rewesi
Dide Oluwa ko ni i pe mo o
Ayanfe duro.
156. Ope, ope, Iyin, Iyin
The Full Lyrics
Ope, ope, Iyin, Iyin
Alleluyah, ogo ni fun Baba
157. Ko s’ohun t’o soro fun O
The Full Lyrics
Ko s’ohun t’o soro fun O
Oba t’Oji Lasaru, oku ojo kerin.
b) Oba ti O we were Gadara san
d) Oba t’O wo abirun Betasda san
e) Oba ti O rin l’ori omi okun.
e) Oba t’O la oju awon afoju.
e) Oba ti O mu ki isun eje gbe.
f) Oba ti O jinde l’ojo keta
158. Onise ara l’Olorun mi
The Full Lyrics
Onise ara l’Olorun mi (2x)
Oun ni Alfa at’ Omega
onise Oro l’Olorun mi
B) Onise ara, onise-iyanu
Onise ara l’Olorun mi
159. B’aye bi mi leere
The Full Lyrics
B’aye bi mi leere:
ki l’o n pa mi l’erin?
Maa da won l’ohun pe:
Mo ni Baba (3x)
b) Ki lo n mu ‘nu mi dun?
d) Ki lo n fun mi l’ayo?
160. Awa n dupe, Baba
The Full Lyrics
Awa n dupe, Baba
Awa n dupe, Omo
Emi Mimo, O se, Ti Re ni ogo.
b) Awon okunrin yin O
Awon obinrin yin O
Metalokan, O se
Ti Re ni ogo
161. Olola t’o ga ju ni Jesu
The Full Lyrics
Olola t’o ga ju ni Jesu
Ke Alleluyah, Amin
Olola t’o ga ju ni Jesu
Ke Alleluyah, Amin
162. O n bo l’awosanma
The Full Lyrics
O n bo l’awosanma
Gbogbo oju ni yoo ei I
At’awon t’o gun Un l’oko
Pel’awon t’o de E l’ade
163. Emi o yin In titi lae
The Full Lyrics
Emi o yin In titi lae
Titi lae, titi lae (2x)
b) Maa yin Oluwa, titi laelae (2x)
164. ‘Tori Olorun n be l’oke
The Full Lyrics
‘Tori Olorun n be l’oke
Eru ko ba mi (2x)
165. Tesiwaju, ma rewesi
The Full Lyrics
Tesiwaju, ma rewesi
Oye ye Oluwa, yoo si dara
Tesiwaju, ma rewesi
Oye ye Oluwa, yoo si dara
b) Tesiwaju, ma se beru
Jesu Kristi mo o (2x)
Yoo si dara
166. Jesu n pe o, ore maa bo
The Full Lyrics
Jesu n pe o, ore maa bo
Wa wole s’odo Baba
Ibi itura
ii) Jesu n pe o
O ni ki o wa gba igbala
iii) Jesu n pe o o, ore maa bo
Asan l’adun aye
Ohun gbogbo a d’opin
iv) Jesu n pe o, arakunrin
Jesu n pe o, arabinrin
Jesu n pe o, O n pe mi o
K’a wa s’apeja eniyan.
167. Mo fe de orun rere, ilu ayo
The Full Lyrics
Mo fe de orun rere, ilu ayo
Bibeli l’o n rohin b’o ti dara to.
168. Emi o royin
The Full Lyrics
Emi o royin (2x)
Emi o royin ife eni t’O gba mi la.
169. Di Jesu mu, sa gbekele E
The Full Lyrics
Di Jesu mu, sa gbekele E
Oun yoo gbo, oju ko ni ti o
170. Awa de – Awa de o
The Full Lyrics
Awa de – Awa de o (2x)
A de o – Awa de o
Awa de o – Jesu Kristi awa de o
171. Jesu wa s’aye lati nwa gb’elese
The Full Lyrics
Jesu wa s’aye lati nwa gb’elese
Eni to ba wa, Jesu ko ni i ta a nu.
172. Mo sinmi le Jesu mo l’ayo
The Full Lyrics
Mo sinmi le Jesu mo l’ayo
Ayo at’alaafia ‘lo n ba mi gbe
O mu ‘nu mi dun, o pa mi l’erin
Dajudaju o, Olorun ododo ni
173. Mo duro lor’Oro Olorun
The Full Lyrics
Mo duro lor’Oro Olorun
Oro Olorun l’agbara (2x)
174. Iyin ye Olorun wa
The Full Lyrics
iyin ye Olorun wa
Oba t’O n dahun adura (2x)
b) Iyin ye Olorun wa
Oba t’O n dahun adura (2x)
175. Kin l’ere f’eniyan t’o ba j’ogun aye
The Full Lyrics
Kin l’ere f’eniyan t’o ba j’ogun aye (2x)
T’o j’ogun aye t’o wa so emi re nu (2x)
Kin l’ere f’eniyan t’o ba j’ogun aye.
176. Imanuel’ wa n’bi
The Full Lyrics
Imamuel’ wa n’bi (2x)
Ogo f’Ooko Re.
177. Gbe Olorun Re ga
The Full Lyrics
Gbe Olorun Re ga (3x)
Iwo okan mi.
178. Emi yoo wa’le jinle si i
The Full Lyrics
Emi yoo wa’le jinle si i
Ife Jesu dun pupo
Emi yoo wa’le jinle si, jinle si i.
179. Hosana l’oke orun
The Full Lyrics
Hosana l’oke orun (2x)
Awon angeli n ko’rin
Hosana loke orun.
b) Pe Jesu l’O ga julo (2x)
Awon angeli n ko’rin
Pe Jesu l’O ga julo
180. Iyanu, iyanu
The Full Lyrics
Iyanu, iyanu (2x)
Iynu, iyanu, l’Olorun wa
181. Iwo l’ope ye, O se o
The Full Lyrics
Iwo l’ope ye, O se o
Messiah.
182. Jesu lowo Re l’o wa (2x)
The Full Lyrics
Jesu lowo Re l’o wa (2x)
Gbogbo agbara (2x)
Jesu lowo Re l’o wo
183. O dara, O tobi, Olorun wa
The Full Lyrics
O dara, O tobi, Olorun wa
O dara, O tobi, Olorun wa
184. Eni ba, eni ba, eni ba m’oore Re
The Full Lyrics
Eni ba, eni ba, eni ba m’oore Re
K’o ba mi gbe Jesu ga
185. Taa la ba fi O we
The Full Lyrics
Taa la ba fi O we
Taa lo le ba O dogba (2x)
Olorun to j’olorun lo
Taa la ba fi O we?
186. Wiwa ti mo l’aaye, aanu Re ha ko
The Full Lyrics
Wiwa ti mo l’aaye, aanu Re ha ko?
Wiwa ti mo l’aaye, ogo f’Ooke Re.
187. Iwo t’o n fe ba Jesu lo
The Full Lyrics
Iwo t’o n fe ba Jesu lo
Gba Jesu, k’o si bo sinu ayp Re
a) Jesu l’ona, otito, iye t’O lo s’odo Baba
Ona miiran ‘o yato s’eyi, opin Re je iku
Gba Jesu l’onii, ki o si bo s’inu ayo Re. Alleluyah
b) Enikeni t’o ba gb’Oro Re, t’o ba si gba A gbo
Onitohun ko ni i wa ‘dajo, ko tun ni i j’ejo mo
O ti Re ‘ku koja bo s’iye ainipekun. Alleluyah.
188. Ayo Olorun ni agbara mi
The Full Lyrics
Ayo Olorun ni agbara mi (3x)
Ayo Olorun ni agbara mi
a) O fun mi l’omi iye
oungbe ko gbe mi mo (3x)
Ayo Olorun ni agbara mi
b) O fun mi l’ounje iye
Ebi ko pa mi mo (3x)
Ayo Olorun ni agbara mi
d) O gbe mi s’ejika Re
Eru ko ba mi mo
Ayo Olorun ni agbar mi.
e)O pa mi lerin ayo
Ha ha ha ha ha (3x
Ayo Olorun ni agbara mi..
189. S’o fe Jesu?
The Full Lyrics
S’o fe Jesu? – A! mo fe Jesu
S’o fe Jesu? – A! mo fe Jesu
S’o fe Jesu? –
Alleluyah, awa yoo ri Oluwa
Alleluyah nigba t’o ba mu wa re’le
Alleluyah, awa yoo ri Oluwa
Alleluyah nigba t’o ba mu wa re’le
190. Alagbara, alagbara, l’Olorun ti mo n sin
The Full Lyrics
Alagbara, alagbara, l’Olorun ti mo n sin
B’O ba soro, A mu u se
Oun l’Alewilese
191. A fi ope fun Oluwa awon Oluwa
The Full Lyrics
A fi ope fun Oluwa awon Oluwa
‘Tori aanu Re duro titi laelae
A fi ope fun Oluwa awon Oluwa
192. Se E l’Oba awon Oba
The Full Lyrics
Se E l’Oba awon Oba (2x)
E mu ade Oba Re wa o
Se E l’Oba awon oba
b) Se E l’Oba, l’Oba o
l’Oba o, Awon oba o
E se Jesu l’Oba, Oba awon oba
Eni t’O ku gfun wa, t’O jiya n’tori wa
A de E l’ade egun
A gun Un l’oko l’egbe
A tu’to si I l’ara nitori ese araye
Oba awon oba, o-o-o
Se E l’Oba, l’Oba o
l’Oba, awon oba o
193. E yin Oluwa, Ara
The Full Lyrics
E yin Oluwa, Ara
E yin Oluwa, Alewilese ni.
194. Igba gbogbo sa l’ayo mi
The Full Lyrics
Igba gbogbo sa l’ayo mi (2x)
satani lo n’ibanuje o
Igba gbogbo sa l’ayo mi
195. A de joba orun
The Full Lyrics
A de jobaa orun (4x)
Eni ba ronupiwada
A de joba orun.
196. E so f’araye, pe Jesu n bo
The Full Lyrics
E so f’araye, pe Jesu n bo (3x)
Eyin omo-ogun, e d’amure giri
197. Kalfari so mi d’otun, mo yege
The Full Lyrics
Kalfari so mi d’otun, mo yege
Ibanuje mi ti fo lo
Gbogbo omije mi ni Jesu nu kuro
Kalfari so mi dotun.
198. Lae lodo Oluwa
The Full Lyrics
Lae lodo Oluwa
Amin, Bee ni k’o ri
Iye n be ninu Oro naa
Aiku ni titi lae.
199. O ti se e fun mi
The Full Lyrics
O ti se e fun mi (2x)
Jesu se e fun mi (2x)
O’un ti baba ko le se
O ti se e fun mi
b) Ohun t’iya ko le se
d) Ohun t’oRe ko le se
e) Ohun t’omo ko le se.
200. Jesu ja sekeseke mi
The Full Lyrics
Jesu ja sekeseke mi
Mo ku, O so mi d’alaaye
Eje Re iyebiye
Oun l’o fi ra mi pada.
a) E wa ba mi yo, ara,
E ba mi yin Jesu logo,
Eni to f’eje Re ra mi,
Lowoesu at’ogun Re.
b) Nigba ti mo so ‘reti nu,
Nigba t’iranwo eda pin,
Mo gb’ohun Jesu to n wi pe:
“wa, omo, iwo o si ye”
d) Iwa rere ko le gba o,
Esin re ko le gba o,
Lyrics found using:
- list of yoruba gospel songs lyrics
- Yoruba new year song
- Title of this yoruba song ohun ti aye pe ni pipe yiya ni lodo re o kin pede o kin tete de akoko to to loma n de